By Taiwo Adeyemi
Sọjí Adétúnjí ọmọ ilẹ̀ ìgbìmọ̀ asojúsòfin
Oríṣun Àwòrán: Nigerian Tribune
Àhẹ̀sọ: Fọ́nrán kan tó léde lójú òpó X láti ọwọ́ Anambra 1st Son ṣàlàyé pé àwọn èèyàn ìlú Adà, ìjọba ìbílẹ̀ Bórípé dènàde ọmọ ilẹ̀ ìgbìmọ̀ asojúsòfin, láti fìyà jẹ́.
Ábájáde: Ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn olùgbé ìlú Adà ṣàlàyé pé ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún kò wáyé, àtẹ̀jáde láti ọwọ agbẹnusọ ọmọ ilẹ̀ ìgbìmọ̀ asojúsòfin ọ̀hún tako àhèsọ náà. Kòsí àrídájú pé wọ́n ṣẹ́ kọlù sì ọmọ ilẹ̀ ìgbìmọ̀ asojúsòfin náà ní’lú Adà.
Àlàyé Lẹ́kùńrẹ́rẹ́
Látàrí ìpèníjà ọ̀rọ̀ ajé, ọ̀wọ́n gógó ọjà àti ebi nílẹ̀ Nàìjíríà, púpò àwọn ọmọ ilẹ̀ yìí ló ti bẹnu àtẹ́ lu àwọn olóṣèlú fún ìwà fàmílétè ti wọ́n gbé pẹ̀lú owó ìlú.
Ní ọjọ́ kẹtà, oṣù kẹfà, ọdún 2024 ni aṣàmúlò ojú òpó X kan, Anambra 1st Son pín fọ́nrán pé àwọn èèyàn ìlú Adà, ìjoba ìbílẹ̀ Bórípé, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun dènà de ọmọ ilẹ̀ ìgbìmọ̀ asojúsòfin, tí wọ́n ṣì fìyà jẹ́.
Sọjí Adétúnjí ni ọmọ ilé ìgbìmọ̀ asojúsòfin tó sojú ẹkùn ìdìbò ìjọba àpapọ̀ Odọ-Ọ̀tìn/Bórípé/Ìfẹ́lódùn nílé ìgbìmọ̀ asojúsòfin.
Nínú fọ́nrán ọ̀hún ni ẹnìkan ti sọ̀rọ̀ kòbákùngbé.
“Kò ní dárafún gbogbo wọn, àwọn wèrè”.
Ẹnìkan nínú fọ́nrán ọ̀hún ló sá àsálà fún ẹ̀mí rèé, tí wọ́n ṣàlàyé gẹ́gẹ́bí asòfin ọ̀hún.
Ní ọjọ́ ketalelogun, oṣù kẹjọ , ọdún 2024 àwọn aṣàmúlò ojú òpó X tí wón tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ààdọ́sán ti wo fọ́nrán náà, tí àwọn aṣàmúlò tótó ẹgbẹ̀rún kan ti pín, àwọn aṣàmúlò ẹgbẹ̀rún méjì ti fẹ́ràn rẹ̀.
Àwọn aṣàmúlò ojú òpó yìí ti fohùn léde lórí fọ́nrán náà.
@dallas ṣàlàyé pé kòsí ǹǹkan tí àwọn òtòṣì yóò jẹ, wọn yóò padà jẹ àwọn olówó.
“Nígbà tí kò bá ṣí ǹǹkan ti àwọn òtòṣì yóò jẹ, àwọn olówó ni wọ́n je. Láìpẹ́ àwọn aláìní yóò lọ sílé wọn níkọ̀kan”
Aṣàmúlò mìíràn @e.u.j náà fèsì sì ọ̀rọ̀ fọ́nrán ọ̀hún pé báyìí ló yẹ kí wọ́n ṣe ìdájọ́ àwọn ọ̀daràn olóṣèlú.
“Báyìí ló yẹ kí wọ́n ṣe fún gbogbo àwọn ọ̀daràn olóṣèlú láti òkè dé’lè.
DUBAWA pinnu láti ṣe ìwádìí fọ́nrán ọ̀hún to rí bí ọ̀rọ̀ náà ṣe gbẹgẹ́ tó.
Ìfìdíòdodomúlẹ̀
A lo Google Reverse Image láti ṣe ìwádìí àwọn àwòrán inú fónrán ọ̀hún. Àbájáde sì fìdí rẹ̀ múlè pé fọ́nrán ọ̀hún lé de sójú òpó Instagram ní ọjọ́ kẹtàlá, oṣù kẹfà ọdún 2024 láti ọwọ́ nairablog.9ja tó ṣàlàyé pé àwọn olùgbé àgbègbè tínúbí ṣẹ̀kọlù sì ọmọ ilẹ̀ ìgbìmọ̀ asojúsòfin tókù nà láti mú àwọn ìlérí ìpolongo ṣe.
A tún kàn sí olùgbé Alómi ní’lú Adà, Arákùnrin Adésínà Olúwọlé, lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, ó ṣàlàyé pé òhun kò gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.
“irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò lè wáyé ní’lú Adà ká mà gbọ́”
“Mo tún ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ mi nígbo’ro, wọ́n ṣàlàyé pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò wá yé ní’lú Adà kí á má mọ̀”.
A tún kàn sí olùgbé ìlú Adà mìíràn, Arákùnrin Olúsẹ́gun Adékúnlé lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, ó ṣàlàyé pé oríṣiríṣi àwọn èèyàn tí pé láti ìlú Èkó, Ìbàdàn àti láti ilé òkèèrè lórí fọ́nrán ọ̀hún.
Ó tèsíwájú pé “Àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ bóyá lóòótọ́ ni àwọn èèyàn ìlú Adà na ọmọ ilẹ̀ ìgbìmọ̀ asojúsòfin àmó kòsí irú ìṣẹ̀lẹ̀ yí ní’lú Adà”.
“Mo ti gba ìpè láti ìlú Èkó, ìlú Ìbàdàn àti àwọn èèyàn wa nílẹ̀ òkèèrè bóyá ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé ní’lú Adà”.
“Kò sí àrídájú pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé ní’lú Adà, èmi kò gbọ́ pé àwọn ará ìlú Adà ṣẹ̀kọlù sì ọmọ ilẹ̀ ìgbìmọ̀ asojúsòfin”.
Bákannáà, nínú àtẹ́jáde tí olùrànlọ́wọ́ lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn fún ọmọ ilẹ̀ ìgbìmọ̀ asojúsòfin tó sojú ẹkùn ìdìbò ìjọba àpapọ̀ Odò-Ọ̀tìn/Bórípé/Ìfẹ́lódùn, Nurudeen Abọ́lájí ṣàlàyé pé ó jé ǹǹkan tí kò tọ́ bí àwọn èèyàn kan gbé kiri pé wọ́n ṣẹ̀kọlù sí Sọjí Adétúnjí ní’lú Adà”.
Ó tèsíwájú pé “ Adétúnjí ló wá láti ìlú Ìbàdàn sí’lù Adà fún ayẹyẹ ìgbéyàwó lọ́jọ́ Àbámẹ́ta tọmọkùnrin ìkan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú rẹ́”.
“Àwọn ọ̀dọ́ láti ìlú Ìkìrun, Áágba àti Adà ló wọ́ yá jà àmó ìjà ọ̀hún ló lágbára nígbà tí ọmọ ilẹ̀ ìgbìmọ̀ asojúsòfin dé bẹ̀”.
“Kòsí ǹǹkan tó kan (Adétúnjí) tàbí ẹgbẹ́ òsèlú PDP, ìjà lásán láàárín àwọn ọ̀dọ́ Ìfẹ́lódùn, Ìkìrun, Ìrágbìjí, Bórípé, àti Áágba. Kòsí èyíkéyìí nínú àwọn ọkọ̀ tó tẹ̀lé asòfin tí wón bàjẹ́ bóyá ara àwọn ọkọ̀ tí wón wà níbi ayẹyẹ ọ̀hún ni wọ́n bàjẹ́.
Àkótán
Ìwádìí fihàn pé kòsí ìkọlù tó wáyé sì ọmọ ilẹ̀ ìgbìmọ̀ asojúsòfin ní’lú Adà nípa ẹ̀rí àwọn èèyàn kan ní’lú ọ̀hún àti àtẹ́jáde láti ọwọ agbẹnusọ fún ọmọ ilẹ̀ ìgbìmọ̀ asojúsòfin ní ẹkún ìdìbò náà. Ófégé ni àhèsọ náà tó le ṣini lọ́nà.
Olùwádìí yìí ṣe ìfìdíòdodo yìí múlẹ̀ láti jẹ́ kí òtítọ́ múlẹ̀ nínú iṣẹ́ ìròyìn àti láti fún òtítọ lágbára lórílẹ̀-èdè.